Bitkoini Dà bí

Láti ọwọ́ Oleg Andreev 2017/12/10open in new window

Bitkoini dàbí owó: kò ṣé yípadà bẹ́ ẹ̀ ni ìkápá rẹ lówà lati tọ́ jú. To bá sọ àpò owò ẹ nù, o ti sọ owò ẹ nù pẹ̀lú. O lè mú bitkoini fuń èyàn kó bá ẹ mu dání, á dàbi pé èyàn fi sí ilé-ìfowópamọ́: o ní láti ní ìdánilójú pé wọ́ n ò ní gbé owó ẹ sálọ.

Bitkoini kò tún dàbí owó: oye tóbá wù ẹ́ lo lè fi pamọ́ bẹ́ẹ̀ni kò ní gba àyè kankan. O lè fi ránṣẹ́ ní orí ìlà sí ẹnikẹ́ni. Kò lè ṣeé ṣe láti ṣe ayédèrú ẹ̀. O kò lè fún ni ní ìṣẹ́jú àáyá kan: láti ri dájú pé ìdúǹádúrà ṣẹlè, o ni láti dúró ìṣẹ́jú méwá sí mẹ́ẹ̀dógún fún ètò náà láti fún ẹ ní ẹ̀rí.

Bitkoini dàbí wúrà: kò kín ṣe ǹkan tí èyàn kàn lè tẹ̀ jáde bí ó ṣe wùyàn, dí ẹ̀ ni oye ẹ̀ tó wà àti pé oye yí fọ́ nká kákìkiri. Làti ní bitkoini èyàn kan gbọ́ dọ̀ fún ẹ, tàbí kí o wàá. Bí wúrà, bitkoini náà ma ń dán: Ó n fa àwọn èyàn mọ́ ra pẹ̀ lú ẹwá ẹ̀ rọ ẹ̀ , óní èdè ètò àdéhùn nínú, àti ìlérí òmìnira l'áìlo ipá fi yínilọ́ kàn padà.

Bitkoini kò tún dàbí wúrà: nípasẹ̀ wíwa ìṣura tí ó létò ni ọ̀ nà kan tí ó wà láti rí bitkoini (tí o jẹ́ pé ọ̀ pọ̀ lọpọ̀ bitkoini ní á lè rọ ní wákàtí kan). Ìdánilójú wà pé ẹnìkan kò lè ṣà dédé rí òkitì tàbí kí ó lọ wàá ní ìsọ̀ gbè-oòrùn. A ní láti tún ìṣòro bitkoini tò kí ó lè dọ́ gba sí akitiyan wíwà ẹ̀ láti mú ètò náà má yẹ̀, tí ò rí bẹ̀ ní ọ̀rọ̀ wúrà. O lè fi ọjọ́ kan wa wúra, ṣùgbọ́n kò lè ṣéṣe pèlú bitkoini bí ó ti wù kí àwọn ẹ̀rọ kòmpútà yára tó. Ètò akitiyan wíwa ìṣura kàn lè yẹ̀ dí ẹ̀ ni (ìtàkùn ètò yí ma tún ìṣòro títẹ búlọ́kù mẹ́fà tò ní àárín wákàtí kan, ṣùgbọ́n tí ìtàkùn ètò yí bá gbòrò dada ó lè tẹ búlọ́ kù méje sí mẹ́ jọ ní àárín wákàtí kan).

Bitkoini dàbí ilè-ìfowópamọ́: A ní ẹ̀rọ kòmpútà, àpamọ́ àkọsílẹ̀ àti ìdúnàdúrà. Àpamọ́ àkọsílẹ̀ yí ló n tọ́ jú gbogbo oye tá ti sọn wọlé àti sọn síta: èló ni tani fi ránṣẹ́ si tani. Orí ẹ̀ rọ ni gbogbo ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀. Kò sí yàrá ìpamọ́ tó kún fún wúrà tàbí àpótí ìfowópamọ́ àdáni, àfi ìpamọ ‘àkọsílẹ̀ t'ìnáwó' kan ṣoṣo.

Bitkoini kò tún dàbí ilè-ìfowópamọ́ : gbogbo ènìyàn lè mọ̀ dájú pé ǹkan tó wà nínú àpamọ́ àkọsílẹ̀ wọn náà ló wà nínú àkọsílẹ̀ t’ìnáwó bí ti gbogbo èyàn tó kù. Kò sí alákòóso tí ó ṣe ìmúdójúìwọ̀n àti ìdánilóju pé ẹnikẹ́ni ò ti ọwọ́ bọ àkọsílẹ̀ t’ìnáwó. Ẹnikẹ́ni lè ṣí oye àpò ìfowópamọ́ tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ni gbogbo àpò ìfowópamọ́ yí ni ó jẹ́ aláìlórúkọ (àfi tí èyàn bá fẹ́ fi ara ẹ̀ hùn). Àkọsílẹ̀ t’ìnáwó yí kò kí n gba orúkọ sílẹ̀ àfi oye tí o ní àti nọ́ mbà ìfowópamọ́ . Kò sí àyè fún 'à ń fi ìdá mélòó kan sílẹ̀ fún ìṣura ilé-ìfowópamọ́ ’ tí wọ́ n fi ń yá àwọn èyàn lówó ju oye ti ilé- ìfowópamọ́ ní lọ. Ní pàtó, kò sí gbèsè nínú àkọsílẹ̀ t’ìnáwó ti bitkoini: bóyá o ní owó ní àdírẹ́sì ẹ, tí owó náà jẹ́ tì ẹ tàbí ìwọ ò ní, tí o dẹ̀ ri lò rrárá Ní àfikún, bitkoini fi àyè sílẹ̀ láti ti owó pa pẹ̀lú 'àwọn ìwé àdéhùn’: àwọn ohun ìrújú tí a ṣe láti ma tan ìpinu ṣíṣe ká l'àárín àwọn ènìyàn tàbí ní àkókò kan pàtó.

Bitkoini dàbí eré ìdárayá Mònópólì: owó ẹyọ ò kín ṣe owó gangan tí kò n'íye lórí. Àwọn èyàn d'íye le nítorí wọ́n yan eré ìdárayá náà láàyò. Ní pàtó, bẹ́ ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú wúrà tàbí irúfẹ́ owó míràn.

Bitkoini kò tún dàbí eré ìdárayá Mònópólì: oye dí ẹ̀ ni àmì ayò tí ó wà bẹ́ẹ̀ni kò sí ẹni tí ó lè ṣe ayédèrú wọn. Èyí ló mú wọn wà ní ipò ìṣura tí gbogbo èyàn dámọ̀ bí wúrà tàbí owó fàdákà.

Bitkoini dàbí Git: ní Git (ètò tó ń ṣe ìṣàkóso ẹ̀yà) àwọn àyípadà ẹ ní ètò nínù okùn tí olùyípadà n dá àbò bò. Tí o bá gbẹ́kẹ̀le olùyípadà titun, o lè rí gbogbo àwọn àlàyé ti tẹ́lẹ̀ (tàbí dí ẹ̀ lára ẹ̀) láti èyíkéyí orísun, kí o sì tún ri dájú wípé ó jẹ́ ohun tí ò ń retí. Bákanáà, ní Bitkoini, gbogbo ìdúnàdúrà ni a tò sínú okùn kan (blockchain) àti pé tí a bá ti fọwọ́ si, ibi yì ó wù kí wọ́ n fi pamọ́ sí, o lè fi ọkàn tán búlọ́ kúṣenì tí ó wù ẹ́ nípasẹ̀ yí yẹ okùn olùyípadà tí ó sopọ̀ mọ́ olùyípadà tí o ti fi ọkàn tán tẹ́lẹ̀ wò. Èyí ló mún ìpamọ́ tí a ti pín ṣiṣẹ́ àti pé o ń mún àyẹ̀wò òtítọ́ rọrún.

Bitkoini kò tún dàbí Git: ní ọ̀nà tí gbogbo ènìyàn gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka kan. Ní Git gbogbo èyàn lè ní oríṣiríṣi ẹ̀ka àti oríta kí o ṣì pa wọ́n pọ̀. Ní Bitkoini a ò lè pa àwọn oríta yí pọ̀. Búlọ́ kúṣenì jẹ́ igi ìtàn àkọsílẹ̀ ti ìdúnàdúrà, ṣùgbọ́ n nígbàgbogbo ẹ̀ ka to tóbi jùlọ ma ń wà (tí ó oye lórí) àti àwọn ẹ̀ka kékèké tí ó kàn lè jẹyọ (tí kò ní gùn ju búlọ́kù kan sí méjì) wọ́n ò ní oye lórí rárá. Ní Git àkóonu ṣekókó ju àwọn ẹ̀ ka lọ, ní Bitkoini ìṣọ̀ kan ṣekókó ju àkóonu lọ.

Bitkoini dàbí Bittorrent: ìtàkùn yí ní alákòóso púpọ̀ , kò sí ibi-ìtẹwó tàbí ilé-ìfowópamọ kankan. Búlọ́ kúṣenì náà dà bí fáìlì kan ní orí bittorrent: ó ní òhùntẹ̀ bẹ́ ẹ̀ ni ó wà ní orí ọ̀ pọ̀ lọpọ̀ ẹ̀ rọ kòmpútà. Ànfàní kan náà ni gbogbo àwọn olùkópa àti àwọn tí ó n wa ìṣura ní. Tí apá kan nínú ìtàkùn náà bá ní ìdálọ́ wọ́ dúró, àwọn ìdúnàdúrà lè gba àwọn apá tó kùn lọ, kódà, tí gbogbo ìtàkùn bá wálẹ̀, àlàyé nípa gbogbo ìdúnàdúra ṣì wà ní ìpamọ ní orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̀rún kọ̀mpútà bẹ́ẹ̀ni owó ẹnikẹ́ni ò sọnù. Nígbàtí àwọn èyàn bá tún padà pàdé lórí ìlà, wọ́n ma bẹ̀rẹ̀ ìdúnàdúra bi wípé ǹkan kan kò ṣẹlẹ̀. Bitkoini àti Bittorrent lè yè ogun ìparun nítorí àlàyé kò lè di ìtànsàn ìmọ́ lẹ̀ àti pé ǹkan tí a lè ṣe nígbàmi ni.

Bitkoini kò tún dàbí Bittorrent: dípò ọ̀ pọ̀ lọpọ̀ fáìlì tí ó dá dúró, fáìlì kan wà tí ó gbòòrò si nígbà gbogbo: ìyẹn ni búlọ́ kúṣenì. Àwọn olùkópa tí ó ṣe pàtàkì jùlọ: ìyẹn àwọn awa-iṣura ni wón gba èrè iṣẹ́ wọn ní owó gidi.

Bitkoini dàbí òmìnira ti ọ̀ rọ̀ : gbogbo ìdúnàdúra dàbí ìfọ̀ rọ̀ ránṣẹ́ ti gbangban tí wọ́ n lè sọ níbikíbi tàbí bí ó ti wù kó rí. Tí àwọn awa-iṣura kan bá gbọ, wọ́ n ma fi sínú búlọ́ kúṣenì bẹ́ èni ìfọ̀ rọ̀ ránṣẹ́ náà ma wa láíláí wà nínú ìtàn. Gbogbo ojú ló ma ri bẹ́ èni kò sí ẹni tí ó lè paárẹ́ .

Bitkoini kò tún dàbí òmìnira ti ọ̀ rọ̀: tí wọ́ n bá ní àtunbọ̀ tán wà. Ìdúnàdúra ló ma ti àwọn ẹyọ owó tí o nílò láti ìbẹ̀ rẹ̀ . Nítoríbẹ̀ kò kín ṣe gbogbo òmùgọ̀ ni a gbà láìyè láti pa ariwo, sùgbọ́ n ka ti ẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀, àwọn tó ní ànfàní láti ní ẹyọ owó nikan ni. Pẹ̀lú ẹ̀, àwọn awa-iṣura lè kọ ìdúnàdúra tí ó bá rújú tàbí oye tóyẹ ká san ò bá tó. Nítoríbẹ̀ kò sí ẹni tí ó fẹ́ fún ẹnikẹ́ni ní òmìnira bí 'otí', sùgbọ́ n gbogbo èyàn ní láti gbìyànjú àti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ látinúwá.

Bitkoini dàbí àdéhùn àjọmọ̀: ó jẹ́ ǹkan àṣà lásán. Ó n ṣiṣẹ́ bí owó níwàn ìgbà tí àwọn èyàn bá ti mu bẹ́ ẹ̀, tí wọ́n dẹ̀ ní ìgboyà láti mu dání àti tí wọ́n bá lè tèlé òfin ẹ̀. A nílò ìmọ̀-ẹ̀rọ nìkan láti ṣe ìlànà àdéhùn náà.

Bitkoini kò tún dàbí àdéhùn àjọmọ̀: kò kín ṣe irú àdéhùn tí wọ́ n kọ́ ni ní ilé-ẹ̀ kọ́ . Kò kín ṣé túnṣe bọ̀ rọ̀ , bẹ́ ẹ̀ ni kò kín ṣe ǹkan tí olórí kan lè fi ipá ṣe. Ka ṣá nípé wọ́ n jẹ́ àwọn òfin aláìlèyídapà tí gbogbo èyàn mú láti ma tèlé fún rara wọn. Nítorínà, ó ti di àdéhùn gbogboògbò.

Bitkoini dàbí idán ti owó ayélujára: bẹ́ ẹ̀ náà lórí.

Awọn onitumọ
Oladele Falese

Olufowosi
BitMEX